[index]yoruba

Ìkéde káríayé fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn


Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ

Bí ó ti jẹ́ pé ṣíṣe àkíyèsí iyì tó jẹ́ àbímọ́ fún ẹ̀dá àti ìdọ́gba ẹ̀tọ́ ṭí kò ṣeé mú kúrò tí ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan ní, ni òkúta ìpìlẹ̀ fún òmìnira, ìdájọ́ òdodo àti àlàáfíà lágbàáyé,
Bí ó ti jẹ́ pé àìka àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn sí àti ìkẹ́gàn àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ti ṣe okùnfà fún àwọn ìwà búburú kan, tó mú ẹ̀rí‐ọkàn ẹ̀dá gbọgbẹ́, tó sì jẹ́ pé ìbẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé titun, nínú èyí tí àwọn ènìyàn yóò ti ní òmìnira òrọ̀ sísọ àti òmìnira láti gba ohun tó bá wù wọ́n gbọ́, òmìnira lọ́wọ́ ẹ̀rù àti òmìnira lọ́wọ́ àìní, ni a ti kà sí àníyàn tó ga jù lọ lọ́kàn àwọn ọmọ‐èniyàn,
Bí ó ti jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì kí a dáàbò bo àwọn ẹ̀tó ọmọnìyàn lábẹ́ òfin, bí a kò bá fẹ́ ti àwọn ènìyàn láti kọjú ìjà sí ìjọba ipá àti ti amúnisìn, nígbà tí kò bá sí ọ̀nà àbáyọ mìíràn fún wọn láti bèèrè ẹ̀tọ́ wọn,
Bí ó ti jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì kí ìdàgbàsókè ìbáṣepọ̀ ti ọ̀rẹ́‐sí‐ọ̀rẹ́ wà láàrin àwọn orílẹ̀‐èdè,
Bí ó ti jẹ́ pé gbogbo ọmọ Àjọ‐ìsọ̀kan orílẹ̀‐èdè àgbáyé tún ti tẹnu mọ́ ìpinnu tí wọ́n ti ṣe tẹ́lẹ̀ nínú ìwé àdéhùn wọn, pé àwọn ní ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn tó jẹ́ kò‐ṣeé‐má‐nìí, ìgbàgbọ́ nínú iyì àti ẹ̀yẹ ẹ̀dá ènìyàn, àti ìgbàgbọ́ nínú ìdọ́gba ẹ̀tọ́ láàrin ọkùnrin àti obìnrin, tó sì jẹ́ pé wọ́n tún ti pinnu láti ṣe ìgbélárugẹ ìtẹ̀síwájú àwùjọ nínú èyí tí òmìnira ètò ìgbé‐ayé rere ẹ̀dá ti lè gbòòrò sí i,
Bí ó ti jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Àjọ‐ìsọ̀kan orílẹ̀‐èdè àgbáyé ti jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fọwọ́ṣowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Àjọ náà, kí won lè jọ ṣe àṣeyege nípa àmúṣẹ àwọn ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti òmìnira ẹ̀dá tó jẹ́ kò‐ṣeé‐má‐nìí àti láti rí i pé à ń bọ̀wọ̀ fún àwọn ẹ̀tọ́ náà káríayé,
Bí ó ti jẹ́ pé àfi tí àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira wọ̀nyí bá yé ènìyàn nìkan ni a fi lè ní àmúṣẹ ẹ̀jẹ́ yìí ní kíkún,
Ní báyìí,
Àpapọ̀ ìgbìmọ̀ Àjọ‐ìsọ̀kan orílẹ̀‐èdè àgbáyé ṣe ìkéde káríayé ti ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, gẹ́gẹ́ bí ohun àfojúsùn tí gbogbo ẹ̀dá àti orílẹ̀‐èdè jọ ń lépa lọ́nà tó jẹ́ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan àti ẹ̀ka kọ̀ọ̀kan láwùjọ yóò fi ìkéde yìí sọ́kàn, tí wọn yóò sì rí i pé àwọn lo ètò‐ìkọ́ni àti ètò‐ẹ̀kọ́ láti ṣe ìgbélárugẹ ìbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ àti òmìnira wọ̀nyí. Bákan náà, a gbọdọ̀ rí àwọn ìgbésẹ̀ tí ó lè mú ìlọsíwájú bá orílẹ̀‐èdè kan ṣoṣo tàbí àwọn orílẹ̀‐èdè sí ara wọn, kí a sì rí i pé a fi ọ̀wọ̀ tó jọjú wọ àwọn òfin wọ̀nyí, kí àmúlò wọn sì jẹ́ káríayé láàrin àwọn ènìyàn orílẹ̀‐èdè tó jẹ́ ọmọ Àjọ‐ìsọ̀kan àgbáyé fúnra wọn àti láàrin àwọn ènìyàn orílẹ̀‐èdè mìíràn tó wà lábẹ́ àṣẹ wọn.


Abala kìíní.
Gbogbo ènìyàn ni a bí ní òmìnira; iyì àti ẹ̀tọ́ kọ̀ọ̀kan sì dọ́gba. Wọ́n ní ẹ̀bùn ti làákàyè àti ti ẹ̀rí‐ọkàn, ó sì yẹ kí wọn ó máa hùwà sí ara wọn gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìyá.


Abala kejì.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ànfàní sí gbogbo ẹ̀tọ́ àti òmìnira tí a ti gbé kalẹ̀ nínú ìkéde yìí láìfi ti ọ̀rọ̀ ìyàtọ̀ ẹ̀yà kankan ṣe; ìyàtọ̀ bí i ti ẹ̀yà ènìyàn, àwọ̀, akọ‐n̄‐bábo, èdè, ẹ̀sìn, ètò ìṣèlú tàbí ìyàtọ̀ nípa èrò ẹni, orílẹ̀‐èdè ẹni, orírun ẹni, ohun ìní ẹni, ìbí ẹni tàbí ìyàtọ̀ mìíràn yòówù kó jẹ́. Síwájú sí i, a kò gbọdọ̀ ya ẹnìkẹ́ni sọ́tọ̀ nítorí irú ìjọba orílẹ̀‐èdè rẹ̀ ní àwùjọ àwọn orílẹ̀‐èdè tàbí nítorí ètò‐ìṣèlú tàbí ètò‐ìdájọ́ orílẹ̀‐èdè rẹ̀; orílẹ̀‐èdè náà ìbáà wà ní òmìnira tàbí kí ó wà lábẹ́ ìṣàkóso ilẹ̀ mìíràn, wọn ìbáà má dàá ìjọba ara wọn ṣe tàbí kí wọ́n wà lábẹ́ ìkáni‐lápá‐kò yòówù tí ìbáà fẹ́ dí òmìnira wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀‐èdè.
Abala kẹta.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti wà láàyè, ẹ̀tọ́ sí òmìnira àti ẹ̀tọ́ sí ààbò ara rẹ̀.


Abala kẹrin.
A kò gbọdọ̀ mú ẹnikẹ́ni ní ẹrú tàbí kí a mú un sìn; ẹrú níní àti ò wò ẹrú ni a gbọdọ̀ fi òfin dè ní gbogbo ọ̀nà.


Abala karùn‐ún.
A kò gbọdọ̀ dá ẹnì kẹ́ni lóró tàbí kí a lò ó ní ìlò ìkà tí kò yẹ ọmọ ènìyàn tàbí ìlò tó lè tàbùkù ẹ̀dá ènìyàn.


Abala kẹfà.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ pé kí a kà á sí gẹ́gẹ́ bí ènìyàn lábẹ́ òfin ní ibi gbogbo.


Abala keje.
Gbogbo ènìyàn ló dọ́gba lábẹ́ òfin. Wọ́n sì ní ẹ̀tọ́ sí àà bò lábẹ́ òfin láìsí ìyàsọ́tọ̀ kankan. Gbogbo ènìyàn ló ní ẹ̀tọ́ sí ààbò tó dọ́gba kúrò lọ́wọ́ ìyàsọ́tọ̀ yòówù tí ìbáà lòdì sí ìkéde yìí àti ẹ̀tọ́ kúrò lọ́wọ́ gbogbo ohun tó bá lè ti ènìyàn láti ṣe irú ìyàsọ́tọ̀ bẹ́ẹ̀.


Abala kẹjọ.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan lórílẹ̀‐èdè, ló ní ẹ̀tọ́ sí àtúnṣe tó jọjú ní ilé‐ẹjọ́ fún ìwà tó lòdì sí ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn, tó jẹ́ kò‐ṣeé‐má‐nìí gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lábẹ́ òfin àti bí òfin‐ìpìlẹ̀ ṣe là á sílẹ̀.


Abala kẹsàn‐án.
A kò gbọdọ̀ ṣàdédé fi òfin mú ènìyàn tàbí kí a kàn gbé ènìyàn tì mọ́lé, tàbí kí a lé ènìyàn jáde ní ìlú láìnídìí.


Abala kẹwàá.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan tí a bá fi ẹ̀sùn kàn ló ní ẹ̀tọ́ tó dọ́gba, tó sì kún, láti ṣàlàyé ara rẹ̀ ní gban̄gba, níwájú ilé‐ẹjọ́ tí kò ṣègbè, kí wọn lè ṣe ìpinnu lórí ẹ̀tọ́ àti ojúṣe rẹ̀ nípa irú ẹ̀sùn ọ̀ràn dídá tí a fi kàn án.


Abala kọkànlá.
1. Ẹnìkẹ́ni tí a fi ẹ̀sùn kàn ni a gbọdọ̀ gbà wí pé ó jàrè títí ẹ̀bi rẹ̀ yóò fi hàn lábẹ́ òfin nípasẹ̀ ìdájọ́ tí a ṣe ní gban̄gba nínú èyí tí ẹni tí a fi ẹ̀sùn kàn yóò ti ní gbogbo ohun tí ó nílò láti fi ṣe àwíjàre ara rẹ̀.
2. A kò gbọdọ̀ dá ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹnìkẹ́ni fún pé ó hu ìwà kan tàbí pé ó ṣe àwọn àfojúfò kàn nígbà tó jẹ́ pé lásìkò tí èyí ṣẹlẹ̀, irú ìwà bẹ́ẹ̀ tàbí irú àfojúfò bẹ́ẹ̀ kò lòdì sí òfin orílẹ̀‐èdè ẹni náà tàbí òfin àwọn orílẹ̀‐èdè àgbáyé mìíràn. Bákan náà, ìjẹníyà tí a lè fún ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ kò gbọdọ̀ ju èyí tó wà ní ìmúlò ní àsìkò tí ẹni náà dá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.


Abala kejìlá.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ pé kí a má ṣàdédé ṣe àyọjúràn sí ọ̀rọ̀ ìgbésí ayé rẹ̀, tàbí sí ọ̀rọ̀ẹbí rẹ̀ tàbí sí ọ̀rọ̀ ìdílé rẹ̀ tàbí ìwé tí a kọ sí i; a kò sì gbọdọ̀ ba iyì àti orúkọ rẹ̀ jẹ́. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí ààbò lábẹ́ òfin kúrò lọ́wọ́ irú àyọjúràn tàbí ìbanijẹ́ bẹ́ẹ̀.


Abala kẹtàlá.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti rìn káàkiri ní òmìnira kí ó sì fi ibi tó bá wù ú ṣe ìbùgbé láàrin orílẹ̀‐èdè rẹ̀.
2. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti kúrò lórílẹ̀‐èdè yòówù kó jẹ́, tó fi mọ́ orílẹ̀‐èdè tirẹ̀, kí ó sì tún padà sí orílẹ̀‐èdè tirẹ̀ nígbà tó bá wù ú.


Abala kẹrìnlá.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti wá ààbò àti láti jẹ àn fàní ààbò yìí ní orílẹ̀‐èdè mìíràn nígbà tí a bá ń ṣe inúnibíni sí i.
2. A kò lè lo ẹ̀tọ́ yìí fún ẹni tí a bá pè lẹ́jọ́ tó dájú nítorí ẹ ṣẹ̀ tí kò jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ ìṣèlú tàbí ohun mìíràn tí ó ṣe tí kò bá ète àti ìgbékalẹ̀ Ajọ‐ìsọ̀kan orílẹ̀‐èdè àgbáyé mu.


Abala kẹẹ̀ẹ́dógún.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀‐èdè kan.
2. A kò lè ṣàdédé gba ẹ̀tọ́ jíjẹ́ ọmọ orílẹ̀‐èdè ẹni lọ́wọ́ ẹnìkẹ́ni láìnídìí tàbí kí a kọ̀ fún ẹnìkẹ́ni láti yàn láti jẹ́ ọmọ orílẹ̀‐èdè mìíràn.


Abala kẹrìndínlógún.
1. Tọkùnrin tobìnrin tó bá ti bàlágà ló ní ẹ̀tọ́ láti fẹ́ ara wọn, kí wọ́n sì dá ẹbí ti wọn sílẹ̀ láìsí ìkanilápá‐kò kankan nípa ẹ̀yà wọn, tàbí orílẹ̀‐èdè wọn tàbí ẹ̀sìn wọn. Ẹtọ́ wọn dọ́gba nínú ìgbeyàwó ìbáà jẹ́ nígbà tí wọn wà papọ̀ tàbí lẹ́yìn tí wọ́n bá kọ ara wọn.
2. A kò gbọdọ̀ ṣe ìgbeyàwó kan láìjẹ́ pé àwọn tí ó fẹ́ fẹ́ ara wọn ní òmìnira àtọkànwá tó péye láti yàn fúnra wọn.
3. Ẹbí jẹ́ ìpìlẹ̀ pàtàkì àdánidá ní àwùjọ, ó sì ní ẹ̀tọ́ pé kí àwùjọ àti orílẹ̀‐èdè ó dáàbò bò ó.


Abala kẹtàdínlógún.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti dá ohun ìní ara rẹ̀ ní tàbí láti ní in papọ̀ pẹ̀lú àwọn mìíràn.
2. A kò lè ṣàdédé gba ohun ìní ẹnì kan lọ́wọ́ rẹ̀ láìnídìí.


Abala kejìdínlógún.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira èrò, òmìnira ẹ̀rí‐ọkàn àti òmìnira ẹ sìn. Ẹtọ́ yìí sì gbani láàyè láti pààrọ̀ ẹ sìn tàbí ìgbàgbọ́ ẹni. Ó sì fún ẹyọ ẹnì kan tàbí àkójọpọ̀ ènìyàn láàyè láti ṣe ẹ̀sìn wọn àti ìgbàgbọ́ wọn bó ṣe jẹ mọ́ ti ìkọ́ni, ìṣesí, ìjọ́sìn àti ìmúṣe ohun tí wọ́n gbàgbọ́ yálà ní ìkọ̀kọ̀ tàbí ní gban̄gba.


Abala kọkàndínlógún.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí òmì nira láti ní ìmọ̀ràn tí ó wù ú, kí ó sì sọ irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ jáde; ẹ̀tọ́yìí gbani láàyè láti ní ìmọ̀ràn yòówù láìsí àtakò láti ọ̀dọ̀ ẹnìkẹ́ni láti wádìí ọ̀rọ̀, láti gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ ẹlòmíràn tàbí láti gbani níyànjú lọ́nàkọ́nà láìka ààlà orílẹ̀‐èdè kankan kún.


Abala ogún.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí òmìnira láti pé jọ pọ̀ àti láti dara pọ̀ mọ́ àwọn mìíràn ní àlàáfíà.
2. A kò lè fi ipá mú ẹnìkẹ́ni dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ kankan.


Abala kọkànlélógún.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti kópa nínú ìṣàkóso orílẹ̀‐èdè rẹ̀, yálà fúnra rẹ̀ tàbí nípasẹ̀ àwọn aṣojú tí a kò fi ipá yàn.
2. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ tó dọ́gba láti ṣe iṣẹ́ ìjọba ní orílẹ̀‐èdè rẹ̀.
3. I fẹ́ àwọn ènìyàn ìlú ni yóò jẹ́ òkúta ìpìlẹ̀ fún à ṣẹ ìjọba; a ó máa fi ìfẹ́ yìí hàn nípasẹ̀ ìbò tòótọ́ tí a ó máa dì láti ìgbà dé ìgbà, nínú èyí tí ẹnì kọ̀ọ̀kan yóò ní ẹ̀tọ́ sí ìbò kan ṣoṣo tí a dì ní ìkọ̀kọ̀ tàbí nípasẹ̀ irú ọ nà ìdìbò mìíràn tí ó bá irú ìdìbò bẹ́ẹ̀ mu.


Abala kejìlélógún.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà nínú àwùjọ ló ní ẹ̀tọ́ sí ìdáàbò bò láti ọwọ́ ìjọba àti láti jẹ́ àn fà ní àwọn ẹ̀tọ́ tí ó bá ọrọ̀‐ajé, ìwà láwùjọ àti àṣà àbínibí mu; àwọn ẹ̀tọ́ tí ó jẹ́ kò‐ṣeé‐má‐nìí fún iyì àti ìdàgbàsókè ẹ̀dá ènìyàn, nípa akitiyan nínú orílẹ̀‐èdè àti ìfọwọ́ṣowọ́ pọ̀ láàrin àwọn orílẹ̀‐èdè ní ìbámu pẹ̀lú ètò àti ohun àlùmọ́nì orílẹ̀‐èdè kọ̀ọ̀kan.


Abala kẹtàlélógún.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti ṣiṣẹ́, láti yan irú iṣẹ́ tí ó wù ú, lábẹ́ àdéhùn tí ó tọ́ tí ó sì tún rọrùn, kí ó sì ní ààbò kúrò lọ́wọ́ àìríṣẹ́ ṣe.
2. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti gba iye owó tí ó dọ́gba fún irú iṣẹ́ kan náà, láìsí ìyàsọ́tọ̀ kankan.
3. Ẹnì kọ̀ọ̀kan tí ó bá ń ṣisẹ́ ní ẹ̀tọ́ láti gba owó oṣù tí ó tọ́ tí yóò sì tó fún òun àti ẹbí rẹ̀ láti gbé ayé tí ó bu iyì kún ènìyàn; a sì lè fi kún owó yìí nípasẹ̀ oríṣìí àwọn ètò ìrànlọ́wọ́ mìíràn nígbà tí ó bá ye.
4. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti dá ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ sílẹ̀ àti láti dara pọ̀ mọ́ irú ẹgbẹ; bẹ́ẹ̀ láti dáàbò bo àwọn ohun tí ó jẹ ẹ́ lógún.


Abala kẹrìnlélógún.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí ìsinmi àti fàájì pẹ̀lú àkókò tí kò pọ̀ jù lẹ́nu iṣẹ́ àti àsìkò ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́ láti ìgbà dé ìgbà tí a ó sanwó fún.


Abala kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti gbé ìgbé ayé tó bójú mu nínú èyí tí òun àti ẹbí rẹ̀ yóò wà ní ìlera àti àlàáfíà, tí wọn yóò sì ní oúnjẹ, aṣọ, ilégbèé, àti àn fàní fún ìwòsàn àti gbogbo ohun tó lè mú ẹ̀dá gbé ìgbé ayé rere. Bákan náà, ẹnì kọ̀ọ̀kan ló tún ní ààbò nígbà àìníṣẹ́lọ́wọ́, nígbà àìsà n, nígbà tó bá di aláàbọ̀‐ara, ní ipò opó, nígbà ogbó rẹ̀ tàbí ìgbà mìíràn tí ènìyàn kò ní ọ̀nà láti rí oúnjẹ òò jọ́, tí eléyìí kì í sì í ṣe ẹ̀bi olúwa rẹ̀.
2. A ní láti pèsè ìtọ́jú àti ìrànlọ́wọ́ pàtàkì fún àwọn abiyamọ àti àwọn ọmọdé. Gbogbo àwọn ọmọdé yóò máa jẹ àwọn àn fàní ààbò kan náà nínú àwùjọ yálà àwọn òbí wọn fẹ́ ara wọn ni tàbí wọn kò fẹ́ ara wọn.


Abala kẹrìndínlọ́gbọ̀n.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láti kọ́ ẹ̀kọ́. Ó kéré tán, ẹ̀kọ́ gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀fẹ́ ní àwọn ilé‐ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Ẹkọ́ ní ilé‐ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ yìí sì gbọdọ̀ jẹ́ dandan. A gbọdọ̀ pèsè ẹ̀kọ́ iṣẹ́‐ọwọ́, àti ti ìmọ̀‐ẹ̀rọ fún àwọn ènìyàn lápapọ̀. Àn fàní tó dọ́gba ní ilé‐ẹ̀kọ́ gíga gbọdọ̀ wà ní àrọ́wọ́tó gbogbo ẹni tó bá tọ́ sí.
2. Ohun tí yóò jẹ́ ète ẹ̀kọ́ ni láti mú ìlọsíwájú tó péye bá ẹ̀dá ènìyàn, kí ó sì túbọ̀ rí i pé àwọn ènìyàn bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àwọn òmìnira wọn, tó jẹ́ kò‐ṣeé‐má‐nìí. E tò ẹ̀kọ́ gbọdọ̀ lè rí i pé ẹ̀mí; ìgbọ́ra‐ẹni‐yé, ìbágbépọ̀ àlàáfíà, àti ìfẹ́ ọ̀rẹ́‐sí‐ọ̀rẹ́ wà láàrin orílẹ̀‐èdè, láàrin ẹ̀yà kan sí òmíràn àti láàrin ẹlẹ́sìn kan sí òmíràn. E tò‐ẹ̀kọ́ sì gbọdọ̀ kún àwọn akitiyan Àjọ‐ìsọ̀kan orílẹ̀‐èdè àgbáyé lọ́wọ́ láti rí i pé àlàáfíà fìdí múlẹ̀.
3. Àwọn òbí ló ní ẹ̀tọ́ tó ga jù lọ láti yan ẹ̀kọ́ tí wọ́n bá fẹ́ fún àwọn ọmọ wọn.


Abala kẹtàdínlọ́gbọ̀n.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ láìjẹ́ pé a fi ipá mú un láti kópa nínú àpapọ̀ ìgbé ayé àwùjọ rẹ̀, kí ó jẹ ìgbádùn gbogbo ohun àmúṣẹ wà ibẹ̀, kí ó sì kópa nínú ìdàgbàsókè ìmọ̀ sáyẹ́n sì àti àwọn àn fàní tó ń ti ibẹ̀ jáde.
2. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí ààbò àn fàní ìmọyì àti ohun ìní tí ó jẹ yọ láti inú iṣẹ́ yòówù tí ó bá ṣe ìbáà ṣe ìmọ̀ sáyẹ́n sì, ìwé kíkọ tàbí iṣẹ́ ọnà.


Abala kejìdínlọ́gbọ̀n.
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní ẹ̀tọ́ sí ètò nínú àwùjọ rẹ̀ àti ní gbogbo àwùjọ àgbáyé níbi tí àwọn ẹ̀tọ́ òmìnira tí a ti gbé kalẹ̀ nínú ìkéde yìí yóò ti jẹ́ mímúṣẹ.


Abala kọkàndínlọ́gbọ̀n.
1. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló ní àwọn ojúṣe kan sí àwùjọ, nípasẹ̀ èyí tí ó fi lè ṣeé ṣe fún ẹni náà láti ní ìdàgbàsókè kíkún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ènìyàn.
2. O fin yóò de ẹnì kọ̀ọ̀kan láti fi ọ̀wọ̀ àti ìmọyì tí ó tọ́ fún ẹ̀tọ́ àti òmìnira àwọn ẹlòmíràn nígbà tí ẹni náà bá ń lo àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira ara rẹ̀. E yí wà ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tó yẹ, tó sì tọ́ láti fi báni lò nínú àwùjọ fún ire àti àlàáfíà àwùjọ náà nínú èyí tí ìjọba yóò wà lọ́wọ́ gbogbo ènìyàn.
3. A kò gbọdọ̀ lo àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira wọ̀nyí rárá, ní ọ̀nà yòówù kó jẹ́, tó bá lòdì sí àwọn ète àti ìgbékalẹ̀ Ajọ‐àpapọ̀ orílẹ̀‐èdè agbáyé.


Abala ọgbọ̀n.
A kò gbọdọ̀ túmọ̀ ohunkóhun nínú ìkéde yìí gẹ́gẹ́ bí ohun tí ó fún orílẹ̀‐èdè kan tàbí àkójọpọ̀ àwọn ènìyàn kan tàbí ẹnìkẹ́ni ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ohunkóhun tí yóò mú ìparun bá èyíkéyìí nínú àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira tí a kéde yìí.
[index]